Surah Al-Araf Verse 155 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Arafوَٱخۡتَارَ مُوسَىٰ قَوۡمَهُۥ سَبۡعِينَ رَجُلٗا لِّمِيقَٰتِنَاۖ فَلَمَّآ أَخَذَتۡهُمُ ٱلرَّجۡفَةُ قَالَ رَبِّ لَوۡ شِئۡتَ أَهۡلَكۡتَهُم مِّن قَبۡلُ وَإِيَّـٰيَۖ أَتُهۡلِكُنَا بِمَا فَعَلَ ٱلسُّفَهَآءُ مِنَّآۖ إِنۡ هِيَ إِلَّا فِتۡنَتُكَ تُضِلُّ بِهَا مَن تَشَآءُ وَتَهۡدِي مَن تَشَآءُۖ أَنتَ وَلِيُّنَا فَٱغۡفِرۡ لَنَا وَٱرۡحَمۡنَاۖ وَأَنتَ خَيۡرُ ٱلۡغَٰفِرِينَ
(Ànábì) Mūsā sì yan àádọ́rin ọkùnrin nínú ìjọ rẹ̀ fún àkókò tí A fún un (láti wá tọrọ àforíjìn fún àwọn ènìyàn rẹ̀. Nígbà tí wọ́n dé ibi àpáta Sīnā’), ohùn igbe líle t’ó mi ilẹ̀ tìtì sì gbá wọn mú, ó sọ pé: “Olúwa mi, tí O bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, Ìwọ ìbá ti pa àwọn àti èmi rẹ́ ṣíwájú (kí á tó wá síbí); ṣé Ìwọ yóò pa wá rẹ́ nítorí ohun tí àwọn òmùgọ̀ nínú wa ṣe ni? Kí ni ohun (tí wọ́n ṣe) bí kò ṣe àdánwò Rẹ; Ò ń fi ṣi ẹni tí O bá fẹ́ lọ́nà, O sì ń tọ́ ẹni tí O bá fẹ́ sọ́nà. Ìwọ ni Aláàbò wa. Nítorí náà, foríjìn wá, kí O sì kẹ́ wa. Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn aláforíjìn