Surah Al-Araf Verse 155 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Arafوَٱخۡتَارَ مُوسَىٰ قَوۡمَهُۥ سَبۡعِينَ رَجُلٗا لِّمِيقَٰتِنَاۖ فَلَمَّآ أَخَذَتۡهُمُ ٱلرَّجۡفَةُ قَالَ رَبِّ لَوۡ شِئۡتَ أَهۡلَكۡتَهُم مِّن قَبۡلُ وَإِيَّـٰيَۖ أَتُهۡلِكُنَا بِمَا فَعَلَ ٱلسُّفَهَآءُ مِنَّآۖ إِنۡ هِيَ إِلَّا فِتۡنَتُكَ تُضِلُّ بِهَا مَن تَشَآءُ وَتَهۡدِي مَن تَشَآءُۖ أَنتَ وَلِيُّنَا فَٱغۡفِرۡ لَنَا وَٱرۡحَمۡنَاۖ وَأَنتَ خَيۡرُ ٱلۡغَٰفِرِينَ
(Anabi) Musa si yan aadorin okunrin ninu ijo re fun akoko ti A fun un (lati wa toro aforijin fun awon eniyan re. Nigba ti won de ibi apata Sina’), ohun igbe lile t’o mi ile titi si gba won mu, o so pe: “Oluwa mi, ti O ba fe bee ni, Iwo iba ti pa awon ati emi re siwaju (ki a to wa sibi); se Iwo yoo pa wa re nitori ohun ti awon omugo ninu wa se ni? Ki ni ohun (ti won se) bi ko se adanwo Re; O n fi si eni ti O ba fe lona, O si n to eni ti O ba fe sona. Iwo ni Alaabo wa. Nitori naa, forijin wa, ki O si ke wa. Iwo si loore julo ninu awon alaforijin