Surah Al-Araf Verse 53 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Arafهَلۡ يَنظُرُونَ إِلَّا تَأۡوِيلَهُۥۚ يَوۡمَ يَأۡتِي تَأۡوِيلُهُۥ يَقُولُ ٱلَّذِينَ نَسُوهُ مِن قَبۡلُ قَدۡ جَآءَتۡ رُسُلُ رَبِّنَا بِٱلۡحَقِّ فَهَل لَّنَا مِن شُفَعَآءَ فَيَشۡفَعُواْ لَنَآ أَوۡ نُرَدُّ فَنَعۡمَلَ غَيۡرَ ٱلَّذِي كُنَّا نَعۡمَلُۚ قَدۡ خَسِرُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ وَضَلَّ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَفۡتَرُونَ
Kí ni wọ́n ń retí bí kò ṣe ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Rẹ̀? Lọ́jọ́ tí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Rẹ̀ bá dé, àwọn t’ó gbàgbé rẹ̀ ṣíwájú yóò wí pé: “Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ Olúwa wa ti mú òdodo wá. Nítorí náà, ǹjẹ́ a lè rí àwọn olùṣìpẹ̀, kí wọ́n wá ṣìpẹ̀ fún wa tàbí kí wọ́n dá wa padà sílé ayé, kí á lè ṣe iṣẹ́ mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí a máa ń ṣe?” Dájúdájú wọ́n ti ṣe ẹ̀mí wọn lófò. Ohun tí wọ́n sì ń dá ní àdápa irọ́ ti di òfò mọ́ wọn lọ́wọ́