Surah Al-Araf Verse 54 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Arafإِنَّ رَبَّكُمُ ٱللَّهُ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٖ ثُمَّ ٱسۡتَوَىٰ عَلَى ٱلۡعَرۡشِۖ يُغۡشِي ٱلَّيۡلَ ٱلنَّهَارَ يَطۡلُبُهُۥ حَثِيثٗا وَٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَ وَٱلنُّجُومَ مُسَخَّرَٰتِۭ بِأَمۡرِهِۦٓۗ أَلَا لَهُ ٱلۡخَلۡقُ وَٱلۡأَمۡرُۗ تَبَارَكَ ٱللَّهُ رَبُّ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Dájúdájú Olúwa yín ni Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sí orí Ìtẹ́-ọlá. Ó ń fi òru bo ọ̀sán lójú, tí òru ń wá ọ̀sán ní kíákíá. Òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ ni wọ́n ti rọ̀ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Gbọ́! TiRẹ̀ ni ẹ̀dá àti àṣẹ. Ìbùkún ni fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá