Surah Al-Adiyat - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
وَٱلۡعَٰدِيَٰتِ ضَبۡحٗا
Allāhu búra pẹ̀lú àwọn ẹṣin t’ó ń sáré t’ó ń mí hẹlẹhẹlẹ ní ojú-ogun
Surah Al-Adiyat, Verse 1
فَٱلۡمُورِيَٰتِ قَدۡحٗا
Ó tún búra pẹ̀lú àwọn ẹṣin tí pátákò ẹsẹ̀ wọn ń ṣáná (níbi eré sísá)
Surah Al-Adiyat, Verse 2
فَٱلۡمُغِيرَٰتِ صُبۡحٗا
Ó tún búra pẹ̀lú àwọn ẹṣin t’ó ń kọlu ọ̀tá ẹ̀sìn ní òwúrọ̀ kùtùkùtù
Surah Al-Adiyat, Verse 3
فَأَثَرۡنَ بِهِۦ نَقۡعٗا
Wọ́n sì fi (pátákò ẹsẹ̀ wọn) tu eruku (ilẹ̀ ọ̀tá) sókè
Surah Al-Adiyat, Verse 4
فَوَسَطۡنَ بِهِۦ جَمۡعًا
Wọ́n tún bẹ́ gìjà papọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ sáààrin àkójọ ọ̀tá
Surah Al-Adiyat, Verse 5
إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ لِرَبِّهِۦ لَكَنُودٞ
Dájúdájú ènìyàn ni aláìmoore sí Olúwa rẹ̀
Surah Al-Adiyat, Verse 6
وَإِنَّهُۥ عَلَىٰ ذَٰلِكَ لَشَهِيدٞ
Dájúdájú Allāhu sì ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórí ìyẹn
Surah Al-Adiyat, Verse 7
وَإِنَّهُۥ لِحُبِّ ٱلۡخَيۡرِ لَشَدِيدٌ
Àti pé dájúdájú ènìyàn le gan-an níbi ìfẹ́ oore ayé
Surah Al-Adiyat, Verse 8
۞أَفَلَا يَعۡلَمُ إِذَا بُعۡثِرَ مَا فِي ٱلۡقُبُورِ
Ṣé kò mọ̀ pé nígbà tí wọ́n bá tú ohun t’ó wà nínú sàréè jáde (fún àjíǹde)
Surah Al-Adiyat, Verse 9
وَحُصِّلَ مَا فِي ٱلصُّدُورِ
tí wọ́n sì tú ohun t’ó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá síta pátápátá
Surah Al-Adiyat, Verse 10
إِنَّ رَبَّهُم بِهِمۡ يَوۡمَئِذٖ لَّخَبِيرُۢ
dájúdájú Olúwa wọn ni Alámọ̀tán nípa wọn ní Ọjọ́ yẹn
Surah Al-Adiyat, Verse 11