Surah Al-Qaria - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
ٱلۡقَارِعَةُ
Àkókò ìjáyà
Surah Al-Qaria, Verse 1
مَا ٱلۡقَارِعَةُ
Kí ni Àkókò ìjáyà
Surah Al-Qaria, Verse 2
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلۡقَارِعَةُ
Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Àkókò ìjáyà
Surah Al-Qaria, Verse 3
يَوۡمَ يَكُونُ ٱلنَّاسُ كَٱلۡفَرَاشِ ٱلۡمَبۡثُوثِ
(Òhun ni) ọjọ́ tí ènìyàn yó dà bí àfòpiná tí wọ́n fọ́nká síta
Surah Al-Qaria, Verse 4
وَتَكُونُ ٱلۡجِبَالُ كَٱلۡعِهۡنِ ٱلۡمَنفُوشِ
àwọn àpáta yó sì dà bí òwú tí wọ́n gbọ̀n dànù
Surah Al-Qaria, Verse 5
فَأَمَّا مَن ثَقُلَتۡ مَوَٰزِينُهُۥ
Nítorí náà, ní ti ẹni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá tẹ̀ wọ̀n
Surah Al-Qaria, Verse 6
فَهُوَ فِي عِيشَةٖ رَّاضِيَةٖ
ó sì máa wà nínú ìṣẹ̀mí t’ó yọ́nú sí
Surah Al-Qaria, Verse 7
وَأَمَّا مَنۡ خَفَّتۡ مَوَٰزِينُهُۥ
Ní ti ẹni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá sì fúyẹ́
Surah Al-Qaria, Verse 8
فَأُمُّهُۥ هَاوِيَةٞ
Hāwiyah sì ni ibùgbé rẹ̀
Surah Al-Qaria, Verse 9
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا هِيَهۡ
Kí sì ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀
Surah Al-Qaria, Verse 10
نَارٌ حَامِيَةُۢ
(Òhun ni) Iná gbígbóná gan-an
Surah Al-Qaria, Verse 11