Surah At-Takathur - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
أَلۡهَىٰكُمُ ٱلتَّكَاثُرُ
Wíwá oore ayé ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ fún ìyanràn ṣíṣe ti kó àìrójú fẹ́sìn ba yín
Surah At-Takathur, Verse 1
حَتَّىٰ زُرۡتُمُ ٱلۡمَقَابِرَ
títí ẹ fi wọ inú sàréè
Surah At-Takathur, Verse 2
كَلَّا سَوۡفَ تَعۡلَمُونَ
Rárá (kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀, àmọ́) láìpẹ́ ẹ máa mọ̀
Surah At-Takathur, Verse 3
ثُمَّ كَلَّا سَوۡفَ تَعۡلَمُونَ
Lẹ́yìn náà, ní òdodo láìpẹ́ ẹ máa mọ̀
Surah At-Takathur, Verse 4
كَلَّا لَوۡ تَعۡلَمُونَ عِلۡمَ ٱلۡيَقِينِ
Bẹ́ẹ̀ ni, tí ó bá jẹ́ pé ẹ ni ìmọ̀ àmọ̀dájú ni (ẹ̀yin ìbá tí ṣe bẹ́ẹ̀)
Surah At-Takathur, Verse 5
لَتَرَوُنَّ ٱلۡجَحِيمَ
Dájúdájú ẹ máa rí iná Jẹhīm
Surah At-Takathur, Verse 6
ثُمَّ لَتَرَوُنَّهَا عَيۡنَ ٱلۡيَقِينِ
Lẹ́yìn náà, dájúdájú ẹ máa rí i ní àrídájú
Surah At-Takathur, Verse 7
ثُمَّ لَتُسۡـَٔلُنَّ يَوۡمَئِذٍ عَنِ ٱلنَّعِيمِ
Lẹ́yìn náà, dájúdájú ní ọjọ́ yẹn wọ́n máa bi yín léèrè nípa ìgbádùn (ayé yìí)
Surah At-Takathur, Verse 8