Surah Al-Asr - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
وَٱلۡعَصۡرِ
Allāhu búra pẹ̀lú àkókò ìrọ̀lẹ́ ayé
Surah Al-Asr, Verse 1
إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ لَفِي خُسۡرٍ
Dájúdájú ènìyàn wà nínú òfò
Surah Al-Asr, Verse 2
إِلَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ وَتَوَاصَوۡاْ بِٱلۡحَقِّ وَتَوَاصَوۡاْ بِٱلصَّبۡرِ
Àyàfi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ òdodo láààrin ara wọn, tí wọ́n sì tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ sùúrù láààrin ara wọn
Surah Al-Asr, Verse 3