Surah Al-Humaza - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
وَيۡلٞ لِّكُلِّ هُمَزَةٖ لُّمَزَةٍ
Ègbé ni fún gbogbo abúnilójú-ẹni, abúnilẹ́yìn-ẹni
Surah Al-Humaza, Verse 1
ٱلَّذِي جَمَعَ مَالٗا وَعَدَّدَهُۥ
ẹni tí ó kó owó jọ, tí ó sì kà á lákàtúnkà (láì ná an fẹ́sìn)
Surah Al-Humaza, Verse 2
يَحۡسَبُ أَنَّ مَالَهُۥٓ أَخۡلَدَهُۥ
Ó ń lérò pé dájúdájú dúkìá rẹ̀ yóò mú un ṣe gbére (nílé ayé)
Surah Al-Humaza, Verse 3
كَلَّاۖ لَيُنۢبَذَنَّ فِي ٱلۡحُطَمَةِ
Rárá (kò rí bẹ́ẹ̀). Dájúdájú wọ́n máa kù ú lókò sínú Hutọmọh ni
Surah Al-Humaza, Verse 4
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلۡحُطَمَةُ
Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Hutọmọh
Surah Al-Humaza, Verse 5
نَارُ ٱللَّهِ ٱلۡمُوقَدَةُ
(Òhun ni) Iná Allāhu tí wọ́n ń kò (t’ó ń jò geregere)
Surah Al-Humaza, Verse 6
ٱلَّتِي تَطَّلِعُ عَلَى ٱلۡأَفۡـِٔدَةِ
èyí tí ó máa jó (ẹ̀dá) wọ inú ọkàn lọ
Surah Al-Humaza, Verse 7
إِنَّهَا عَلَيۡهِم مُّؤۡصَدَةٞ
Dájúdájú wọ́n máa ti (àwọn ìlẹ̀kùn) Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá
Surah Al-Humaza, Verse 8
فِي عَمَدٖ مُّمَدَّدَةِۭ
(Wọ́n máa wà) láààrin àwọn òpó kìrìbìtì gíga (nínú Iná)
Surah Al-Humaza, Verse 9