Surah Al-fil - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
أَلَمۡ تَرَ كَيۡفَ فَعَلَ رَبُّكَ بِأَصۡحَٰبِ ٱلۡفِيلِ
Ṣé o ò rí bí Olúwa rẹ ti ṣe ọ̀rọ̀ ìjọ elérin ni
Surah Al-fil, Verse 1
أَلَمۡ يَجۡعَلۡ كَيۡدَهُمۡ فِي تَضۡلِيلٖ
Ṣé kò sọ ète wọn di òfo bí
Surah Al-fil, Verse 2
وَأَرۡسَلَ عَلَيۡهِمۡ طَيۡرًا أَبَابِيلَ
Ó sì rán àwọn ẹyẹ níkọ̀níkọ̀ sí wọn
Surah Al-fil, Verse 3
تَرۡمِيهِم بِحِجَارَةٖ مِّن سِجِّيلٖ
Wọ́n ń jù wọ́n ní òkúta amọ̀ (t’ó ti gbaná sára)
Surah Al-fil, Verse 4
فَجَعَلَهُمۡ كَعَصۡفٖ مَّأۡكُولِۭ
Ó sì sọ wọ́n di bíi èrúnrún koríko àjẹkù gbígbẹ
Surah Al-fil, Verse 5