Surah Quraish - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
لِإِيلَٰفِ قُرَيۡشٍ
(Ìkẹ́ ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu) fún ìdílé Ƙuraeṣ láti wà papọ̀ nínú ààbò
Surah Quraish, Verse 1
إِۦلَٰفِهِمۡ رِحۡلَةَ ٱلشِّتَآءِ وَٱلصَّيۡفِ
(Ìkẹ́ ni sẹ́ láti ọ̀dọ̀ Allāhu) fún wọn láti wà papọ̀ nínú ààbò lórí ìrìn-àjò ní ìgbà òtútù àti ìgbà ooru
Surah Quraish, Verse 2
فَلۡيَعۡبُدُواْ رَبَّ هَٰذَا ٱلۡبَيۡتِ
Nítorí náà, kí wọ́n jọ́sìn fún Olúwa Ilé (Ka‘bah) yìí
Surah Quraish, Verse 3
ٱلَّذِيٓ أَطۡعَمَهُم مِّن جُوعٖ وَءَامَنَهُم مِّنۡ خَوۡفِۭ
Ẹni tí Ó fún wọn ní jíjẹ (ní àsìkò) ebi. Ó sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ nínú ìpáyà
Surah Quraish, Verse 4