Surah Al-Maun - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
أَرَءَيۡتَ ٱلَّذِي يُكَذِّبُ بِٱلدِّينِ
Sọ fún mi nípa ẹni t’ó ń pe Ọjọ́ Ẹ̀san nírọ́
Surah Al-Maun, Verse 1
فَذَٰلِكَ ٱلَّذِي يَدُعُّ ٱلۡيَتِيمَ
Ìyẹn ni ẹni t’ó ń lé ọmọ-òrukàn dànù
Surah Al-Maun, Verse 2
وَلَا يَحُضُّ عَلَىٰ طَعَامِ ٱلۡمِسۡكِينِ
Kò sì níí gbìyànjú láti bọ́ mẹ̀kúnnù
Surah Al-Maun, Verse 3
فَوَيۡلٞ لِّلۡمُصَلِّينَ
Ègbé ni fún àwọn (mùnááfìkí) t’ó ń kírun; kò túmọ̀ sí “ohun t’ó ń run ènìyàn”. Àmọ́ ìtúmọ̀ “ìrun” ni “ohun t’ó ń run ẹ̀ṣẹ̀ olùkírun” nítorí pé tí olùkírun bá ti ṣe àlùwàlá ni ó ti ṣan gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wẹẹrẹ tí ó ti fi àwọn oríkèé ara rẹ̀ ṣe ṣíwájú. Bákan náà
Surah Al-Maun, Verse 4
ٱلَّذِينَ هُمۡ عَن صَلَاتِهِمۡ سَاهُونَ
àwọn t’ó ń gbàgbé láti kírun wọn ní àsìkò rẹ̀
Surah Al-Maun, Verse 5
ٱلَّذِينَ هُمۡ يُرَآءُونَ
àwọn t’ó ń ṣe ṣekárími
Surah Al-Maun, Verse 6
وَيَمۡنَعُونَ ٱلۡمَاعُونَ
àti pé wọ́n ń hánnà ohun èlò (fún àwọn ènìyàn)
Surah Al-Maun, Verse 7