Surah Al-Kauther - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
إِنَّآ أَعۡطَيۡنَٰكَ ٱلۡكَوۡثَرَ
Dájúdájú Àwa fún ọ ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ oore
Surah Al-Kauther, Verse 1
فَصَلِّ لِرَبِّكَ وَٱنۡحَرۡ
Nítorí náà, kírun fún Olúwa rẹ, kí o sì gúnran (fún Un)
Surah Al-Kauther, Verse 2
إِنَّ شَانِئَكَ هُوَ ٱلۡأَبۡتَرُ
Dájúdájú, ẹni t’ó ń bínú rẹ, òun ni kò níí lẹ́yìn
Surah Al-Kauther, Verse 3