Surah Al-Adiyat - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
وَٱلۡعَٰدِيَٰتِ ضَبۡحٗا
Allahu bura pelu awon esin t’o n sare t’o n mi helehele ni oju-ogun
Surah Al-Adiyat, Verse 1
فَٱلۡمُورِيَٰتِ قَدۡحٗا
O tun bura pelu awon esin ti patako ese won n sana (nibi ere sisa)
Surah Al-Adiyat, Verse 2
فَٱلۡمُغِيرَٰتِ صُبۡحٗا
O tun bura pelu awon esin t’o n kolu ota esin ni owuro kutukutu
Surah Al-Adiyat, Verse 3
فَأَثَرۡنَ بِهِۦ نَقۡعٗا
Won si fi (patako ese won) tu eruku (ile ota) soke
Surah Al-Adiyat, Verse 4
فَوَسَطۡنَ بِهِۦ جَمۡعًا
Won tun be gija papo pelu re saaarin akojo ota
Surah Al-Adiyat, Verse 5
إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ لِرَبِّهِۦ لَكَنُودٞ
Dajudaju eniyan ni alaimoore si Oluwa re
Surah Al-Adiyat, Verse 6
وَإِنَّهُۥ عَلَىٰ ذَٰلِكَ لَشَهِيدٞ
Dajudaju Allahu si n je Elerii lori iyen
Surah Al-Adiyat, Verse 7
وَإِنَّهُۥ لِحُبِّ ٱلۡخَيۡرِ لَشَدِيدٌ
Ati pe dajudaju eniyan le gan-an nibi ife oore aye
Surah Al-Adiyat, Verse 8
۞أَفَلَا يَعۡلَمُ إِذَا بُعۡثِرَ مَا فِي ٱلۡقُبُورِ
Se ko mo pe nigba ti won ba tu ohun t’o wa ninu saree jade (fun ajinde)
Surah Al-Adiyat, Verse 9
وَحُصِّلَ مَا فِي ٱلصُّدُورِ
ti won si tu ohun t’o wa ninu igba-aya eda sita patapata
Surah Al-Adiyat, Verse 10
إِنَّ رَبَّهُم بِهِمۡ يَوۡمَئِذٖ لَّخَبِيرُۢ
dajudaju Oluwa won ni Alamotan nipa won ni Ojo yen
Surah Al-Adiyat, Verse 11