Surah Al-Masadd - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
تَبَّتۡ يَدَآ أَبِي لَهَبٖ وَتَبَّ
Ọwọ́ Abu-Lahab méjèèjì ti ṣòfò. Òun náà sì ṣòfò
Surah Al-Masadd, Verse 1
مَآ أَغۡنَىٰ عَنۡهُ مَالُهُۥ وَمَا كَسَبَ
Àwọn dúkìá rẹ̀ àti ohun tí ó ṣe níṣẹ́ (ìyẹn, àwọn ọmọ rẹ̀) kò sì níí rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ (níbi ìyà)
Surah Al-Masadd, Verse 2
سَيَصۡلَىٰ نَارٗا ذَاتَ لَهَبٖ
Ó sì máa wọ inú Iná eléjò fòfò
Surah Al-Masadd, Verse 3
وَٱمۡرَأَتُهُۥ حَمَّالَةَ ٱلۡحَطَبِ
Àti ìyàwó rẹ̀, aláàárù-igi-ìṣẹ́pẹ́ ẹlẹ́gùn-ún, (ó máa wọná)
Surah Al-Masadd, Verse 4
فِي جِيدِهَا حَبۡلٞ مِّن مَّسَدِۭ
Igbà-ọ̀pẹ pọ̀npọ̀nràn máa wà ní ọrùn rẹ̀ (nínú Iná)
Surah Al-Masadd, Verse 5