Surah Al-Falaq - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
قُلۡ أَعُوذُ بِرَبِّ ٱلۡفَلَقِ
Sọ pé: "Mo sá di Olúwa òwúrọ̀ kùtùkùtù
Surah Al-Falaq, Verse 1
مِن شَرِّ مَا خَلَقَ
níbi aburú ohun tí Ó dá
Surah Al-Falaq, Verse 2
وَمِن شَرِّ غَاسِقٍ إِذَا وَقَبَ
àti níbi aburú òru nígbà tí ó bá ṣóòkùn
Surah Al-Falaq, Verse 3
وَمِن شَرِّ ٱلنَّفَّـٰثَٰتِ فِي ٱلۡعُقَدِ
àti níbi aburú àwọn (òpìdán) t’ó ń fẹnu fátẹ́gùn túẹ́túẹ́ sínú àwọn ońdè
Surah Al-Falaq, Verse 4
وَمِن شَرِّ حَاسِدٍ إِذَا حَسَدَ
àti níbi aburú onílara nígbà tí ó bá ṣe ìlara
Surah Al-Falaq, Verse 5