Surah Al-Anaam Verse 61 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Anaamوَهُوَ ٱلۡقَاهِرُ فَوۡقَ عِبَادِهِۦۖ وَيُرۡسِلُ عَلَيۡكُمۡ حَفَظَةً حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءَ أَحَدَكُمُ ٱلۡمَوۡتُ تَوَفَّتۡهُ رُسُلُنَا وَهُمۡ لَا يُفَرِّطُونَ
Òun ni Olùborí t’Ó wà lókè àwọn ẹrú Rẹ̀. Ó sì ń rán àwọn ẹ̀ṣọ́ kan si yín títí di ìgbà tí ikú yóò fi dé bá ẹnì kọ̀ọ̀kan yín. Àwọn Òjíṣẹ́ wa yó sì gba ẹ̀mí rẹ̀, wọn kò sì níí jáfira